HOMAGE TO THE SUPREME ENERGY “OLODUMARE” >>> The Creator of all things.

ORIKI OLODUMARE AND THE ORISAS / IRUNMALES / “THE ENERGIES OF THE UNIVERSE”

HOMAGE TO OLODUMARE >>> The Creator of all things.

Iba lowo Olodumare . Agotan .Oba ateni peleje to fori sagbeji omi.

Oba aseda aye aseda orun. Kos i nkan ti Olodumare ko lese .

Ti oba se ojo ase oda. Ase ikan a mu bi otutu. A se ikan amu bi oye

Oba Ogege a gbayegun. Atobiju Eni Iyanu. Alaafin Orun. Oluwa Orun.

Oba to nse ohun gbogbo. Alakoso Orun . Agbara ayeraye

OBATALA>>>

The Artist of Olodumare. The Spirit of the Ozone layers and the clouds

Obatala Oba tarisa. Oba tapatapa ti bawon gbe temiode Iranje. A fu ruru bi ojo .

Aso enikan di igba eni . Baba Arugbo se temi Orisa se temi

Obatala. Oba tapa tapa ti bawon gbode Iranje. Afun ruru bi ojo .

O so enIkan di igba eni Orisa funfun gboooo.

Orisa nla algogo oje .Alagbo omo. Orisa Olugbon Orisa Ogiyan.

Orisa nla o alagogo oje o Ogbapa oje gege ofi lala ofi lolo.

Ewure idi ege ki je ki won o gun ege. Aguntan idi ege ki je ki won o gun ege.

Olaigbo lo fi ogbon inu mota lo fi imoran mokun . Lo gun ogege igi ola nife.

Ogege igi agunla Obatala gun ogege igi ola lo gun o Ogege igi agunla.

Omo Olufon lola orolu. Orolu aroje seye.

Obo kunkun obo sise o bo orisa kan jigi dare..

Bo nirin nta egbeje .eni ki won maa lo.

Boni baba nta egbefa eni ki won maa lo.

Egberin din logun laa roje nile Olufun.

Oje ye Olorisa. Aso fufu ye Olobatala.

Mo difa memu. Mo siraka j e ru niwe.

Ewu oje ni won fi soro nile Olufon.

O solufun lomo onilu ijege ijege.

Ose Olufun lomo onilu kan ijege ijege.

Oni pele kan ko gbodo

ESU >>>

The dual energy of the universe. The spirit of the good and evil.

Esu laau . Esu Elegbara. Esu Abini . Esu Odara. Esu Onile Orita.

Esu ma se mi esu ma se .Esu ma se mi mo rubo Esu

Latopa Esu. Aso irun iwaju po mo ti pako.

Awon ologun eru won rubo ki Esu ma se awon .

Awon oloji iwofa awon yen nrubo ki Esu ma se awon.

Esu ma se wa omo elomiran ni ki ose.

Eni esu nse bo leyin iwaju iwaju ni yio ma boluware.

Yio fi omo egbon sile omo olomo nI maa mu lo. Ose.

Yio fi omo aburo sile eni eleni ni maa wa lo.

Lang bono ma se wa omo elomira ni ki o se.Ofe bata kujo lamulamu

Olamu lamu baba Esu. Esu ti oni se gbogbo wa lode ileyi lailai.

Ebesu lagado e besu lagbado . Iya oniyangan e besu lagbado.

Ore mi tesu loye kakoko mu gbo. Ore mi tesu loye kakoko mu gbo

Onile orita Odara. Tesu loye kakoko mu gbo.

Tesu lo soro . Belebo nsebo tesu lo soro

Mo gbebo fun bara . tesu losoro. Esu laalu ogbo.

Tesu lo soro.

Onile orita tesu lo soro. Masemi ma se omo mi

Tesu lo soro..

Obelekun sunkun. Keru o ba elekun

Elekun nsunku. Laaroye nseje.

Oni mi nsumi Laroye nsufun.

O nlo laa ala. Atari e fe nfe.

Odara onite orita. Opa npa olamo olopa pasan.

Damu dabo . Adaamu alejo adaamu onile.

Esu dakun ko mase damu awa o.

Abini lesu abini lesu.

OGUN. >>> The Energy of Iron and steel . Energy of Technology. Energy of War and Victory

Ogun Orisa tin be nile.

Og un nbe loko Ogun. Ogun nbe nibode o ti o fi aja bo ori.

Ogun Onire oko mi ejemu Oluwonran .Ogun loko lodo.Oran ti maa mu sumuyumun.

Woru o woru oko .Woru odo. Woru roka feye je. Mo dele mo ro fun baba.

Baba lo ro fun yeye. Labe Ogede labe orombo eti se de abe ate.

Ide were ni to kun . Owu rubutu ni tosa.

Sekeseke ni to gun . E bani kilo fun bale ko ma pe asoja mu wa loja

Gbogbo wa gbogbo wa lo gun jo bi..

Ogun laka aye elegbeje ado. Ogun ma bami ja ere ni ki o ba mise.

Egbe leyin eni a nda loro.. Ogun se bi ere o di baba

O se kaka odi baba agbalagba

Meje logun . Ogun onile ni gbaja. Ogun Onire a gba agbo.

Ogun ikola a je gbin. Ogun mola mola ni gbekuru funfun.

Ogun gbenogbeno oje igi nii mu. Ogun oni gbajamo irun ori nii je.

Ogun onikola a gba eje eniyan

Lakaaye ejemu oluwonran Oro gbe inu ile si dun yunmuyunmu.

Ogun bawa se ko ma bawa ja. Ogun bamise ko ma bawa je.

Talo ni ko to lorisa Ode. Ogun to lorisa Ode. Talo pe ko to lorisa Ode

Ogun to Lorisa Ode.

Ogun lo laso idi mi mo fi nbo ara ni loko. Oro loko lodo abawo yanyan

Laka aye ejemu . Oro ti ru minmini Koriko odo ti ru winiwini .

Ogun ma ba mi ja ere ni ki o ba mise.

Awon alai mokan mokan . Won no bi Ogun ba gba ile gba odo awon yio gba oko lo.

Won ko mo pe Orisa to gbale gbodo o le gba oko lowo eni.

Oro loko lodo a bi awo yoyo.

Ta lo pe koto lorisa kowi Ogun to lorisa Ode.

Bamise ko ma bami ja Ogun bamise ko ma bami ja.

Ogun bamise ko ma bami ja o .

Ogun lakaye Osinmole. Onile kangunkangun ona Orun. Nijo ti Ogun nti ori Oke bo. Aso ina lomu bora ewu eje lo wo sorun. Ogun korobiti korobiti Ogun korobiti korobiti..

Ogun Onire Osinmole. Won no Ire kiise ile Ogun Ogun ya ki won lagbede o wa mu emu ni.

Ogun lakaye Osinmole. Ogun onile ina. Ogun ni onile owo . Ogun ni olodede imo.Ogun dakun mama funmi lomo ole ki je ki eniyan o ni laari. Ogun mama fumi lomo ole kii je ki eniyan begbe pe.

Ogun naa nio wole de ni. Ogun naa nio wole de ni . Eni ran ni lajo ni wole deni.

Ogun Okunrin sansan gele Okunrin sansan gelegele.

Okunrin wa Okunrin wo Okunrin wawa wowo. Okunrin gbonin gbonin

Okunrin gbongbon gele.

Eni ran n i lajo ni wole deni. Ogun naa nio wo le deni.

Nijo Ogun nti ori okee bo . Aso ina lomu bora ewu eje lo wo sorun.

Ogun korobiti Ogun korobiti korobiti.. Moriwo Ogun sara yeye. Ni moro ni mogun Moriwo Ogun sara yeye.

Moriwo sara Ogun yagbayugbu. Ogun nbe lona sawoye.

Oro Ogun ni kowo. Oro Ogun soro. Bi aba ro oka Ki a ko ti Ogun sile.

Bi aba bu iwo isu leno ki atete fi ti Ogun sile.

Nitori Ogun lo ro oko Ogun lo pa juba Ogun lo roko mo isu ti isu fi jina.

Ogun lo loola ti o ko ila si atewo Ogun lo la omo lowo gberegede. Ako oni koleja. Ogun onija oole ejemu oluwere. Ada girigiri re bi ija.

Meje logunn

OSOOSI >>> Energy of the Hunters and the Knowledge of the forest.

Osoosi ohun gangan laburo Ogun Lakaaye osinmale. Omo Iya Ogun ni Osoosi se.

Ebura nla a bi oju kanhun kanhun. Agadagidi eniyan abi kumo lorunOsoosi o .Elegbeje ado o .

Mabamija Ere ni ki o bamise.Ta lo je gbeno wo olukoko loju.

Osoosi ohun gangan la buro Ogun lakaaye Osinmole.

Ode abere ode. Owu Ode.

Oromodiye ode Owududu ode. Ni moro ni mogun.

Ero ya ka kewa wo ohun ode nse.

Ode ti nprin la mbawi Ode ti pa efun .

Ki se ode tin doju bole leyin eranko nibi ti gbe le eranko lo.

Awarawa ri rawao Awa ara wa ri rawa. Bi Ologini ri omo Ekun

Awa ara wa ri ara wa. Kode mama bode ja o.

Kode mama bode ja. Ode Ibadan ati Ode Oyo.

Kode mama bode ja o. Ato de Ibadan atode Oyo Kode mama bode ja o.

Ati Ode Ibadan ati Ode Eko kode mama bode ja o.

Yio jorun la be dodo obe o Yio jorunla be dodo obe.

Ode to regbeo ti ko meranbo yio je Orunla be dodo obe.

Ba tentele ba tentele atioro ba tentele owo tobe ba tetenle.

.

SANGO. >>>

Oba koso Sango Oba kosoOloju orogbo.

Elereke Obi.o Egungun ti yona lenu .

Orisa ti bologbo leru Oko Oya.

Atoba jaye gbege oko Iya Olorogbo.

Elereke obi o. Eni fi oju di o. Sango agbe.Oloju orogbooooooo

Atoba jaye gbege oko Iya Olorogbo Sango Olukoro ooooo.

Oloju orogbo. Sango Alaso Osun o.

Obakoso . Obakoso Orisa Oba koso .

Oloju orogbo bi o ba di oyin ki o ma tami .

Bi o ba dojola ko ma pe ran Iya mi je

Oba koso Sango Oba koso.

Mo so keleo tori torun mo so kele

Sango onibode Oko Oya.

Oko Oya ti yona loju ti yona lenu.

Oko Oya Sago Onibode Oko Oya. 3ce.

Oloju orogbo elereke obi ohoo

Oni na se oko mi o mo ku ise o Oku ise sango oko laya mi Orun.

Oku ise Sango omo Iya mosin.

Sango fee de koloko ma le re oko

Sango fee de kolodo ma le re odo mo.

Ati furufuru wole oko mi otun ti de o.

Asale ni pa ojo eke oko

Bo ba pa oloro a pa ofofo ile.

Afoju ta lose. Sango mi pa alaseju o se lekun mo.

O foju elewure o foju elewure. O foju Alamo o foju e ya mo

Ile alapara ni Sango yio gba.

Odede alapara ni Sango o ma wo .

Omo talapara ba bi ni Sango yio lu pa.

Oko mi ma pami mo fori mi se asun je.

Ori mi ti e ni. Ori ti o nje eja .Ori ti o njeku .

Orii ti o nje eja Ori ti o nje okoko baba agbebo.

Ori Onisango je eye etu mo akuko.

Nbo loke Iya abegun ti jo loke wa.

A lo dudu aso mora. Otiti amilu wo bi ojo.

Bi o panije a kuku pa ni je.

Oke kara ke koro ti so oloro di jijini.

Bi agbon o soro a tidi bole o.

Bi Sango o soro sara ni o ti duro o.

A gesin ka le ado

Bi a peri oko eni a fi ida lale.

Bi Ida re lale bi a mu epo .

O njo gberin a Pe Yemoja bi eni pe Orunmila

E gbo bi won ti npo ni damola. E gbo bi won tip e oni damola bi eni da iyun mo Segi.

Okun lele bi Igba epo. O taja tan o taja erupe.

Oju merindinlogun ni Sango fi nworan.

O nfi mejo se ile aye o nfi mejo se ode Orun.

A gbeno yanju a gbeno yan. Awo ile oloode yanyan

Pee mi bee ni je. E mo pe mori ko gbodo fo.

Rube fori sogi Ajanaku kanri ya mo.

Bi mo bati ri Sango mo le gba egungun loju .

Bi mo ba tiri Sango Mo le ta Orisa laya.

Bi mo ba ti ri Sango kini kan ko ni se emi.

Oko mi Iwo ni mo ri o leyin mo fi ngbegun loju. Erin fola mi o

Pa yan tan fi aja seri. A le pe Sango seun abi ko seun.

Nibo le gbe bami ri Sango erin fola mi. Nibo le gbe bami ri Sango omo Iya mesin

Ari Sango nile reku reku . A ri Sango nile reku reku.

Ari Sango nibi a gbe reye ti a gbe ri oko pa eye. Igba ti aroko areye mo.

Ari Sango nibi agbero remu. Giwa olori wa. Olori Osa ti fir a re ni nakan nakan.

Sango ni nlo loke abe gun jijo loke wa. Sango toju elewure lota .Afonja toju olobo wo sokoto.

Godogodo pa ngodo se e mi naa ni mo loko mi.

Bi Ileya de ma gbe Imole mi de Iba jagilegbo se oogun.

Bi Igbagbo de ma tun Mole mi se

Salubarika iwo loba Iwo niOosa.

Iwo ni otito aye ku si lowo a to agbalagba bu se enu kondu.

Alara moka ti deru ba oju. A pa Abuke ti o diye le aro.

Pafin ki o ba Oosa daro.

Godogodo pan godo se emi naa ni mo ni oko mi.

Oosa ti Timi ori tin bi Ifa re lere.

A ya leyin eni ti oju nkan erinfolami.

Oko mi ma ba mi loju je O po lokunrin.

O fe de Sango fe de amoloko male re fe de a molodo ma leoko .

Sango fe de amolodo ma le re odo.

Yio ba baba eni Sango ko le pa. E niti Sango yio pa lodun meta oni Eran ni fi njiyan.

Pa eniyan tan faja seri .Ile wa lawa ti nberu re.

Sango Ile awa ko tobi Odede wa ko gbaye.

Sango bi gbogbo ile wa po to Gbogbo ole wa ko ka owo eko yangan.

Oko mi Mo pawa ma fori mi se asun je.

Alaramoka oko wa nsodun 2ce Araba nla migbo kiji o . Alaramoka Oko wa ngbodun .

Awa nse Odun idile wa keni owu kobe. Oloosa nse odun idile wa keni o wu ko be..

Eni ti ko dun mo ko rodo ko loo kusi. Awa nse odun idile waa .

Oloju Orogbo Eleeke obi oko Oya.

A sa giri ala giri Ola giri kakaka fi igba edun bo.

Sebi efin ina nla da laye. Ina nbe la lede Orun alakeji.

Oloju Orogbo Oranfe .Onibon Orun.

Sango lonile ina Onibon Orun Owara ja gi aja sonu.

Oloju Orogbo . Sango ma lami laya oSango ma lami laya o .

Agbeno genge a feke lenu ya. Sango de o oro Oko Oya o Agbeno genge a feke lenu ya.

Bi ko ba won nile a wa won rook.

Bi Olubanmi ba na’wo ija de bi ko ba won nile a wa won rook.

Bi Olubanbi ba nawo ija de bi ko ba won nile a wa won rook.

Bi asiyekunle ba nawo ija de bi ko bawon nile a wa won roko

Hey Sango oko mi o Mo ni ki o ma sole si odo mi o Moni ki o ma sole sile baba to bi mi lomo

Ako ta giji Okunrin A fin laya bi Akala .

Akala lofin Sango ofin E be ni mo be o Mo ni ki o ma sola si ede mi.

Omo lile lowo Baba. Ina loju Ina lenu Ina lorule paanu

Ojo kan erin Ojo kan ibinu Jigan bi Kiniun Oko Oya.

Bi a o ri Oya ao ri Sango Ebora Oloju Orogbo.

Ebe ni mo beo Mo ni ki o ma sole si odede mi

Ni mose nke tantan bi omo Awo.

Sango deo Oro Oka Oya o Agbeno genge a feke lenu ya.

error: Content is protected !!